Orin Dafidi 150 - Yoruba YBCV

← Books

Orin Dafidi

Yoruba YBCV
| 6 of 6 verses

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Ọlọrun ninu ibi mimọ́ rẹ̀; yìn i ninu ofurufu oju-ọrun agbara rẹ̀.

2 Yìn i nitori iṣẹ agbara rẹ̀: yìn i gẹgẹ bi titobi nla rẹ̀.

3 Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yìn i.

4 Fi ìlu ati ijó yìn i: fi ohun ọnà orin olokùn ati fère yìn i.

5 Ẹ yìn i lara aro olohùn òke: ẹ yìn i lara aro olohùn goro:

6 Jẹ ki ohun gbogbo ti o li ẹmi ki o yìn Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.